- 1. 2000 ní òǹkà Yorùbá ni___
A) Ẹgbàá rin B) Ẹgbẹrun C) Ogún D) Ẹgbàá
- 2. Kí ni 20,000 ní òǹkà Yorùbá?
A) Ẹgbarun B) Ẹgbàá je C) Ẹgbàá wà D) Ẹgbàafà
- 3. Ohun tí kò tọ́ tí a ṣe sí ọmọlàkejì ni ìwà___
A) Omolúàbí B) Ìdọ̀tí C) Ìkà D) Ọ̀sì
- 4. Ìwọ̀nyí ni ìwà ìkà tí ó wọ́pọ̀ ni ayé àtijọ́ àyàfi___
A) Ìfiniṣọfà B) Ìfiniṣẹrú C) Ìfinirúbọ D) Ìfọmọṣowó
- 5. Ìwà ìkà tí o wọ́pọ̀ lóde òní ni ìwọ̀nyí, àyàfi___
A) Lílo ọmọ nílọ̀kulọ̀ B) Ìjínigbé C) Ìfiniṣọfà D) Ìfiniṣowó
- 6. Ọ̀rọ̀____lè ṣiṣẹ́ olùwà,ẹ̀yán, àti àbọ̀.
A) àpónlé B) Orúkọ C) ìṣẹ D) àpèjúwe
- 7. ____ ni àwọn Yorùbá gbà pé wọ́n ń sọ ọjà di ọ̀wọ́n.
A) Alágbàtà B) Èrò ọjà C) Ọlójà D) Oníbárà
- 8. À n ṣe òwò kí á le____
A) di ìyálọ́jà B) sọ́ọ̀tì C) ríhun ṣe D) jẹ èrè
- 9. Àǹfààní òwò ṣiṣe níwònyí àyàfi; Ó ń mú ____
A) kí a níṣẹ́ ẹni lọ́wọ́ B) kí ìṣẹ́ àti òṣì pòórá C) ẹni di ọ̀lẹ D) kí a tẹpá mọ́ṣẹ́
- 10. ____tàbí káràkátà jẹ́ ọ̀kan nínú ara iṣẹ owó Yoruba.
A) Oúnjẹ jíjẹ B) Òwò ṣíṣe C) Ìwà òtítọ́ D) Aróbọ̀
- 11. Ẹni tí ó ta ọjà tí kò jèrè ni won ní o____
A) ṣòwò sọ́ọ̀ti B) gbìyànjú C) tẹpá mọ́ṣẹ́ D) tàtà jèrè
- 12. Ìwòyí ni iṣẹ tí ọ̀rọ̀ orúkọ le ṣe,ayafi____
A) àbọ̀ B) ẹ̀yán C) olùwà D) òpómúléró
- 13. 'Bàbá Bọ́lá lọ sí oko'. Kí ni ọrọ orúkọ tí o se iṣẹ́ ẹ̀yán nínú gbólóhùn yìí?
A) lọ B) Bàbá C) Bọ́lá D) Oko
- 14. Èwo ni kìí ṣe álífábẹ̀ẹ̀tì ede Yorùbá
A) a B) ae C) b D) o
- 16. Àmì wo ni ó bá ọ̀rọ̀ yí mu? kirakita--d:d:d:d
A) Kìrákítà B) kirakitā C) kirákíta D) Kìràkìtà
- 17. Àmì wo ni ó bá ọ̀rọ̀ yí mu? Dodo--d:d
A) Dọ̀dó B) Dòdò C) Dodo D) Dódó
- 18. Fáwẹ̀lì Yorùbá pín sí:
A) àìgbẹ̀fẹ̀ àti agbẹ̀fẹ̀ B) àìránmúpè ati àrańmúpè C) arẹ́họ́n ati àkùnyùn D) àfúnupè àti aṣẹ́nupè
- 19. Tọ́ka sí ọ̀rọ̀-orúkọ olùwà nínú gbólóhùn yìí: "Ajá bàbá Olú tí jẹ ẹja náà"
A) bàbá B) náà C) Olú D) Ajá
- 20. "Ojó lọ ra ẹja tí yóò jẹ" Tọ́ka sí ọ̀rọ̀-orúkọ àbọ̀ nínú gbólóhùn yìí.
A) ẹja B) Ojo C) ra D) lọ
- 21. "Adébísí pa ẹran màálu jẹ". Èwo ni ọ̀rọ̀-orúkọ tí ó ṣiṣé ẹ̀yán nínú gbólóhùn yìí?
A) Adébísí B) pa C) màálu D) ẹran
- 22. Kí a tó lè di oníṣòwò,a gbọ́dọ̀ ní nǹkan wọnyí àyàfi____.
A) ní ìmọ̀ nípa ọjà ta fẹ tà B) ìdọmọ ẹgbẹ́ ọlọ́jà C) ẹ̀kọ́sẹ́ kátà-kárà D) owó òkòwò
- 23. Fífún òǹràjà ní díẹ̀ jẹ nínú ọjà tí à ń tà ni à ń pè ní_____.
A) ènì B) ìtọ́wọ̀ C) sàn díẹ̀díẹ̀ D) àwín
- 24. Ìwọ̀nyí ni àwọn owó tí a mọ àwọn Yorùbá sì àyàfi_____.
A) Aróbọ̀ B) Ìjínigbé C) Owóróbo D) Aṣọ títa
- 25. ______ni à ń pe àwọn tí n ta ọjà pẹ́ẹ́pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ́.
A) Olóúnjẹ B) Oníwóróbo C) Alájàpá D) Aláróbò
- 26. Ọ̀rọ̀ orúkọ inú gbólóhùn yìí "Motúnráyọ̀ sì tún rápálá wọlé" ni:
A) Motúnráyọ̀ B) wọlé C) si D) tun
- 27. Kọ́ńsónáǹtì tó wà nínú èdè Yorùbá jẹ_____
A) 17 B) 9 C) 10 D) 18
- 28. Èwo ni kọ́ńsónáǹtì tí a fi èjì ètè pè nínú àwọn wọ̀nyí?
A) d B) f C) g D) b
- 29. ___jẹ́ fáwẹ̀lì àyanupẹ̀
A) n B) u C) a D) m
- 30. ___jẹ kọ́ńsónáǹtì àrańmúpè.
A) p B) s C) t D) n
|