- 1. 2000 ní òǹkà Yorùbá ni___
A) Ogún B) Ẹgbàá rin C) Ẹgbẹrun D) Ẹgbàá
- 2. Kí ni 20,000 ní òǹkà Yorùbá?
A) Ẹgbàafà B) Ẹgbàá wà C) Ẹgbarun D) Ẹgbàá je
- 3. Ohun tí kò tọ́ tí a ṣe sí ọmọlàkejì ni ìwà___
A) Ìkà B) Ìdọ̀tí C) Ọ̀sì D) Omolúàbí
- 4. Ìwọ̀nyí ni ìwà ìkà tí ó wọ́pọ̀ ni ayé àtijọ́ àyàfi___
A) Ìfinirúbọ B) Ìfiniṣẹrú C) Ìfiniṣọfà D) Ìfọmọṣowó
- 5. Ìwà ìkà tí o wọ́pọ̀ lóde òní ni ìwọ̀nyí, àyàfi___
A) Ìfiniṣowó B) Ìfiniṣọfà C) Ìjínigbé D) Lílo ọmọ nílọ̀kulọ̀
- 6. Ọ̀rọ̀____lè ṣiṣẹ́ olùwà,ẹ̀yán, àti àbọ̀.
A) ìṣẹ B) Orúkọ C) àpónlé D) àpèjúwe
- 7. ____ ni àwọn Yorùbá gbà pé wọ́n ń sọ ọjà di ọ̀wọ́n.
A) Alágbàtà B) Oníbárà C) Èrò ọjà D) Ọlójà
- 8. À n ṣe òwò kí á le____
A) jẹ èrè B) di ìyálọ́jà C) ríhun ṣe D) sọ́ọ̀tì
- 9. Àǹfààní òwò ṣiṣe níwònyí àyàfi; Ó ń mú ____
A) kí a níṣẹ́ ẹni lọ́wọ́ B) kí a tẹpá mọ́ṣẹ́ C) kí ìṣẹ́ àti òṣì pòórá D) ẹni di ọ̀lẹ
- 10. ____tàbí káràkátà jẹ́ ọ̀kan nínú ara iṣẹ owó Yoruba.
A) Òwò ṣíṣe B) Oúnjẹ jíjẹ C) Ìwà òtítọ́ D) Aróbọ̀
- 11. Ẹni tí ó ta ọjà tí kò jèrè ni won ní o____
A) tàtà jèrè B) tẹpá mọ́ṣẹ́ C) ṣòwò sọ́ọ̀ti D) gbìyànjú
- 12. Ìwòyí ni iṣẹ tí ọ̀rọ̀ orúkọ le ṣe,ayafi____
A) òpómúléró B) ẹ̀yán C) àbọ̀ D) olùwà
- 13. 'Bàbá Bọ́lá lọ sí oko'. Kí ni ọrọ orúkọ tí o se iṣẹ́ ẹ̀yán nínú gbólóhùn yìí?
A) lọ B) Oko C) Bọ́lá D) Bàbá
- 14. Èwo ni kìí ṣe álífábẹ̀ẹ̀tì ede Yorùbá
A) ae B) b C) o D) a
- 16. Àmì wo ni ó bá ọ̀rọ̀ yí mu? kirakita--d:d:d:d
A) kirakitā B) Kìrákítà C) Kìràkìtà D) kirákíta
- 17. Àmì wo ni ó bá ọ̀rọ̀ yí mu? Dodo--d:d
A) Dodo B) Dódó C) Dòdò D) Dọ̀dó
- 18. Fáwẹ̀lì Yorùbá pín sí:
A) arẹ́họ́n ati àkùnyùn B) àìránmúpè ati àrańmúpè C) àfúnupè àti aṣẹ́nupè D) àìgbẹ̀fẹ̀ àti agbẹ̀fẹ̀
- 19. Tọ́ka sí ọ̀rọ̀-orúkọ olùwà nínú gbólóhùn yìí: "Ajá bàbá Olú tí jẹ ẹja náà"
A) Olú B) Ajá C) náà D) bàbá
- 20. "Ojó lọ ra ẹja tí yóò jẹ" Tọ́ka sí ọ̀rọ̀-orúkọ àbọ̀ nínú gbólóhùn yìí.
A) lọ B) Ojo C) ẹja D) ra
- 21. "Adébísí pa ẹran màálu jẹ". Èwo ni ọ̀rọ̀-orúkọ tí ó ṣiṣé ẹ̀yán nínú gbólóhùn yìí?
A) Adébísí B) pa C) màálu D) ẹran
- 22. Kí a tó lè di oníṣòwò,a gbọ́dọ̀ ní nǹkan wọnyí àyàfi____.
A) ìdọmọ ẹgbẹ́ ọlọ́jà B) ní ìmọ̀ nípa ọjà ta fẹ tà C) owó òkòwò D) ẹ̀kọ́sẹ́ kátà-kárà
- 23. Fífún òǹràjà ní díẹ̀ jẹ nínú ọjà tí à ń tà ni à ń pè ní_____.
A) àwín B) ènì C) sàn díẹ̀díẹ̀ D) ìtọ́wọ̀
- 24. Ìwọ̀nyí ni àwọn owó tí a mọ àwọn Yorùbá sì àyàfi_____.
A) Ìjínigbé B) Owóróbo C) Aróbọ̀ D) Aṣọ títa
- 25. ______ni à ń pe àwọn tí n ta ọjà pẹ́ẹ́pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ́.
A) Aláróbò B) Olóúnjẹ C) Oníwóróbo D) Alájàpá
- 26. Ọ̀rọ̀ orúkọ inú gbólóhùn yìí "Motúnráyọ̀ sì tún rápálá wọlé" ni:
A) tun B) wọlé C) Motúnráyọ̀ D) si
- 27. Kọ́ńsónáǹtì tó wà nínú èdè Yorùbá jẹ_____
A) 10 B) 9 C) 18 D) 17
- 28. Èwo ni kọ́ńsónáǹtì tí a fi èjì ètè pè nínú àwọn wọ̀nyí?
A) d B) g C) f D) b
- 29. ___jẹ́ fáwẹ̀lì àyanupẹ̀
A) a B) n C) u D) m
- 30. ___jẹ kọ́ńsónáǹtì àrańmúpè.
A) s B) p C) t D) n
|