- 1. Mélòó ni álífábẹ̀ẹ̀tì konsonanti èdè Yorùbá?
A) 18 B) 15 C) 20 D) 11
- 2. 2000 ní òǹkà Yorùbá ni____
A) Egbèje B) Ogójì C) Ọgbọ̀n D) Ẹgbẹ̀waa
- 3. _____ni orísirísi ọ̀rọ̀ tí à ń lò nínú gbólóhùn
A) Ìsòrí ọ̀rọ̀ B) gbólóhùn C) ewì D) òwe
- 4. Ọ̀rọ̀ tó ń ṣiṣẹ́ Olùwà,àbọ̀, àti ẹ̀yán nínú gbólóhùn èdè Yorùbá ni___
A) Ọ̀rọ̀ àpèjúwe B) Ọ̀rọ̀ orúkọ C) Ọ̀rọ̀ ìṣe D) Ọ̀rọ̀ àpónlé
- 5. Ojú àti imú ń dùn mi. Èwo ni ọ̀rọ̀ àsopọ nínú gbólóhùn yìí?
A) dùn B) àti C) imú D) oju
- 6. Ọnà mélòó ni álífábẹ̀ẹ̀tì èdè Yorùbá pín sí?
A) Mẹ́rin B) Méjì C) Márùn-ún D) Mẹ́ta
- 7. Lẹ́tà fáwẹ̀lì èdè Yorùbá ni_____
A) a,e,ẹ,i,o,ọ,u B) a,m,n,y,j,t C) b,d,g,gb,j,k,m D) a,e,ẹ,y,z,u
- 8. Òpómúléró inú gbólóhùn ni_____
A) Ọ̀rọ̀ onísílébù B) Ọrọ orúkọ C) Ọ̀rọ̀ àpónlé D) Ọ̀rọ̀ ìṣe
- 9. ____ni ọ̀ro tí ó ń tọ́ka sí ìṣèlẹ̀ tàbí ohun ti ẹnìkan ṣe nínú gbólóhùn.
A) Ọ̀rọ̀ àpèjúwe B) Ọ̀rọ̀ àpónlé C) Ọ̀rọ̀ ìṣe D) Ọ̀rọ̀ arọ́pò orúkọ
- 10. 'Mo wá sùgbọ́n ń kò ba yín'. Èwo ni ọ̀rọ̀ àsopọ nínú gbólóhùn yìí?
A) yín B) sùgbón C) ba D) mo wá
- 11. ____ ni àwọn ọ̀rọ̀ tí a fi ń so àwọn ọ̀rọ̀ orúkọ tàbí gbólóhùn pọ̀.
A) Ọ̀rọ̀ atọ́kùn B) Ọ̀rọ̀ ìṣe C) Ọ̀rọ̀ àpónlé D) Ọ̀rọ̀ àsopọ̀
- 12. ____ni egbẹ̀rún ní òǹkà Yorùbá.
A) 10,000 B) 5000 C) 3000 D) 1000
- 13. _____ni àwọn ọ̀rọ̀ tí a fi ń so àwọn ọ̀rọ̀ orúkọ tàbí gbólóhùn pọ̀.
A) Ọ̀rọ̀ àsopọ B) Ọ̀rọ̀ àpèjúwe C) Ọ̀rọ̀ àpọ́nlé D) Ọ̀rọ̀ atọ́kùn
- 14. Kọ́ńsónáǹtì akọ́kọ́ nínú álífábẹ̀ẹ̀tì Yorùbá ni____
A) a B) d C) z D) b
- 15. Lẹ́tà tí ó parí álífábẹ̀ẹ̀tì Yorùbá ni___
A) y B) u C) i D) e
- 16. Álífábẹ̀ẹ̀tì Yorùbá tó wà ní ipò kárùn-ún ni____
A) f B) ẹ C) gb D) b
- 17. Wa ri mi ni Abuja. 'ni' nínú gbólóhùn yi jẹ ọ̀rọ̀____
A) iṣe B) atọ́kùn C) àpọ́nlé D) arọ́po orúkọ
- 18. Fáwẹ̀lì àkọ́kọ́ nínú álífábẹ̀ẹ̀tì Yorùbá ni____
A) o B) i C) a D) ẹ
- 19. Fáwẹ̀lì yìí kìí ṣe ti Yorùbá
A) ọ B) i C) ea D) o
- 20. "Fọláké pupa fòò". fòò nínú gbólóhùn yìí jẹ́ ọ̀rọ̀_____.
A) àpọ́nle B) atọ́kùn C) ẹ̀yán D) ìṣe
- 21. Ọ̀rọ̀-orúkọ àbọ̀ nínú gbólóhùn yìí: "Mo jẹ iyán tán" ni____
A) tan B) jẹ C) Iyan D) mo
- 22. Ọ̀rọ̀-orúkọ tí ó ṣiṣẹ́ ẹ̀yán nínú gbólóhùn yìí: "Ìyàwó Bísí wọ aṣọ òfì" ni____.
A) Bísí B) Ìyá C) wọ D) aṣọ
- 23. _____ni ọ̀rọ̀ tí ó ń tọ́ka iṣẹ tàbí ohun tí ẹnìkan ṣe nínú gbólóhùn.
A) Ọ̀rọ̀ àpọ́nlẹ́ B) Ọ̀rọ̀ ìṣe C) Ọ̀rọ̀ àpèjúwe D) Ọ̀rọ̀ orúkọ
- 24. Ọ̀rọ̀_____ ni a máa n lo rọ́pò ọ̀rọ̀ orúkọ.
A) arọ́pò orúkọ B) àsopọ̀ C) àpèjúwe D) ìṣe
- 25. "Aṣọ funfun ni ìyàwó wọ̀". _____ ni ọ̀rọ̀ àpèjúwe nínú gbólóhùn yìí.
A) Aṣọ B) ni C) Iyawo D) Funfun
- 26. Abi, sùgbọ́n, pẹ̀lú,àti,àmọ́ ni àwọn àpẹẹrẹ ọ̀rọ̀_____.
A) Àsopọ B) Atọ́kùn C) Àpèjúwe D) Arọ́pò
- 27. "Délé ti Ìbàdàn dé lánàá". ____jẹ ọ̀rọ̀ atókùn nínú gbólóhùn yìí
A) Délé B) ti C) lánàá D) ni
- 28. Bí____ kò bá sí nínú gbólóhùn, gbólóhùn bi kò lè ní ìtumọ̀ kíkún.
A) ọ̀rọ̀ orúkọ B) ọ̀rọ̀ atọ́kùn C) ọ̀rọ̀ àpèjúwe D) ọ̀rọ̀ ìṣe
|