- 1. Mélòó ni álífábẹ̀ẹ̀tì konsonanti èdè Yorùbá?
A) 20 B) 15 C) 18 D) 11
- 2. 2000 ní òǹkà Yorùbá ni____
A) Ọgbọ̀n B) Ogójì C) Ẹgbẹ̀waa D) Egbèje
- 3. _____ni orísirísi ọ̀rọ̀ tí à ń lò nínú gbólóhùn
A) òwe B) Ìsòrí ọ̀rọ̀ C) ewì D) gbólóhùn
- 4. Ọ̀rọ̀ tó ń ṣiṣẹ́ Olùwà,àbọ̀, àti ẹ̀yán nínú gbólóhùn èdè Yorùbá ni___
A) Ọ̀rọ̀ ìṣe B) Ọ̀rọ̀ orúkọ C) Ọ̀rọ̀ àpèjúwe D) Ọ̀rọ̀ àpónlé
- 5. Ojú àti imú ń dùn mi. Èwo ni ọ̀rọ̀ àsopọ nínú gbólóhùn yìí?
A) dùn B) oju C) imú D) àti
- 6. Ọnà mélòó ni álífábẹ̀ẹ̀tì èdè Yorùbá pín sí?
A) Mẹ́rin B) Méjì C) Mẹ́ta D) Márùn-ún
- 7. Lẹ́tà fáwẹ̀lì èdè Yorùbá ni_____
A) a,e,ẹ,y,z,u B) b,d,g,gb,j,k,m C) a,e,ẹ,i,o,ọ,u D) a,m,n,y,j,t
- 8. Òpómúléró inú gbólóhùn ni_____
A) Ọ̀rọ̀ ìṣe B) Ọ̀rọ̀ onísílébù C) Ọ̀rọ̀ àpónlé D) Ọrọ orúkọ
- 9. ____ni ọ̀ro tí ó ń tọ́ka sí ìṣèlẹ̀ tàbí ohun ti ẹnìkan ṣe nínú gbólóhùn.
A) Ọ̀rọ̀ arọ́pò orúkọ B) Ọ̀rọ̀ ìṣe C) Ọ̀rọ̀ àpèjúwe D) Ọ̀rọ̀ àpónlé
- 10. 'Mo wá sùgbọ́n ń kò ba yín'. Èwo ni ọ̀rọ̀ àsopọ nínú gbólóhùn yìí?
A) sùgbón B) ba C) mo wá D) yín
- 11. ____ ni àwọn ọ̀rọ̀ tí a fi ń so àwọn ọ̀rọ̀ orúkọ tàbí gbólóhùn pọ̀.
A) Ọ̀rọ̀ àsopọ̀ B) Ọ̀rọ̀ atọ́kùn C) Ọ̀rọ̀ ìṣe D) Ọ̀rọ̀ àpónlé
- 12. ____ni egbẹ̀rún ní òǹkà Yorùbá.
A) 10,000 B) 1000 C) 3000 D) 5000
- 13. _____ni àwọn ọ̀rọ̀ tí a fi ń so àwọn ọ̀rọ̀ orúkọ tàbí gbólóhùn pọ̀.
A) Ọ̀rọ̀ àsopọ B) Ọ̀rọ̀ àpọ́nlé C) Ọ̀rọ̀ àpèjúwe D) Ọ̀rọ̀ atọ́kùn
- 14. Kọ́ńsónáǹtì akọ́kọ́ nínú álífábẹ̀ẹ̀tì Yorùbá ni____
A) z B) a C) b D) d
- 15. Lẹ́tà tí ó parí álífábẹ̀ẹ̀tì Yorùbá ni___
A) y B) i C) u D) e
- 16. Álífábẹ̀ẹ̀tì Yorùbá tó wà ní ipò kárùn-ún ni____
A) gb B) ẹ C) b D) f
- 17. Wa ri mi ni Abuja. 'ni' nínú gbólóhùn yi jẹ ọ̀rọ̀____
A) arọ́po orúkọ B) atọ́kùn C) iṣe D) àpọ́nlé
- 18. Fáwẹ̀lì àkọ́kọ́ nínú álífábẹ̀ẹ̀tì Yorùbá ni____
A) ẹ B) a C) o D) i
- 19. Fáwẹ̀lì yìí kìí ṣe ti Yorùbá
A) ọ B) i C) ea D) o
- 20. "Fọláké pupa fòò". fòò nínú gbólóhùn yìí jẹ́ ọ̀rọ̀_____.
A) ẹ̀yán B) àpọ́nle C) ìṣe D) atọ́kùn
- 21. Ọ̀rọ̀-orúkọ àbọ̀ nínú gbólóhùn yìí: "Mo jẹ iyán tán" ni____
A) mo B) Iyan C) tan D) jẹ
- 22. Ọ̀rọ̀-orúkọ tí ó ṣiṣẹ́ ẹ̀yán nínú gbólóhùn yìí: "Ìyàwó Bísí wọ aṣọ òfì" ni____.
A) wọ B) Ìyá C) Bísí D) aṣọ
- 23. _____ni ọ̀rọ̀ tí ó ń tọ́ka iṣẹ tàbí ohun tí ẹnìkan ṣe nínú gbólóhùn.
A) Ọ̀rọ̀ ìṣe B) Ọ̀rọ̀ orúkọ C) Ọ̀rọ̀ àpèjúwe D) Ọ̀rọ̀ àpọ́nlẹ́
- 24. Ọ̀rọ̀_____ ni a máa n lo rọ́pò ọ̀rọ̀ orúkọ.
A) ìṣe B) àsopọ̀ C) àpèjúwe D) arọ́pò orúkọ
- 25. "Aṣọ funfun ni ìyàwó wọ̀". _____ ni ọ̀rọ̀ àpèjúwe nínú gbólóhùn yìí.
A) Aṣọ B) Iyawo C) ni D) Funfun
- 26. Abi, sùgbọ́n, pẹ̀lú,àti,àmọ́ ni àwọn àpẹẹrẹ ọ̀rọ̀_____.
A) Arọ́pò B) Atọ́kùn C) Àpèjúwe D) Àsopọ
- 27. "Délé ti Ìbàdàn dé lánàá". ____jẹ ọ̀rọ̀ atókùn nínú gbólóhùn yìí
A) lánàá B) ti C) ni D) Délé
- 28. Bí____ kò bá sí nínú gbólóhùn, gbólóhùn bi kò lè ní ìtumọ̀ kíkún.
A) ọ̀rọ̀ ìṣe B) ọ̀rọ̀ atọ́kùn C) ọ̀rọ̀ àpèjúwe D) ọ̀rọ̀ orúkọ
|