- 1. 2000 ní òǹkà Yorùbá ni___
A) Ẹgbàá B) Ẹgbàá rin C) Ẹgbẹrun D) Ogún
- 2. Kí ni 20,000 ní òǹkà Yorùbá?
A) Ẹgbarun B) Ẹgbàafà C) Ẹgbàá je D) Ẹgbàá wà
- 3. Ohun tí kò tọ́ tí a ṣe sí ọmọlàkejì ni ìwà___
A) Ìkà B) Ìdọ̀tí C) Ọ̀sì D) Omolúàbí
- 4. Ìwọ̀nyí ni ìwà ìkà tí ó wọ́pọ̀ ni ayé àtijọ́ àyàfi___
A) Ìfiniṣẹrú B) Ìfọmọṣowó C) Ìfinirúbọ D) Ìfiniṣọfà
- 5. Ìwà ìkà tí o wọ́pọ̀ lóde òní ni ìwọ̀nyí, àyàfi___
A) Ìjínigbé B) Lílo ọmọ nílọ̀kulọ̀ C) Ìfiniṣowó D) Ìfiniṣọfà
- 6. Ọ̀rọ̀____lè ṣiṣẹ́ olùwà,ẹ̀yán, àti àbọ̀.
A) Orúkọ B) àpónlé C) àpèjúwe D) ìṣẹ
- 7. ____ ni àwọn Yorùbá gbà pé wọ́n ń sọ ọjà di ọ̀wọ́n.
A) Èrò ọjà B) Alágbàtà C) Ọlójà D) Oníbárà
- 8. À n ṣe òwò kí á le____
A) ríhun ṣe B) di ìyálọ́jà C) sọ́ọ̀tì D) jẹ èrè
- 9. Àǹfààní òwò ṣiṣe níwònyí àyàfi; Ó ń mú ____
A) kí a níṣẹ́ ẹni lọ́wọ́ B) kí a tẹpá mọ́ṣẹ́ C) ẹni di ọ̀lẹ D) kí ìṣẹ́ àti òṣì pòórá
- 10. ____tàbí káràkátà jẹ́ ọ̀kan nínú ara iṣẹ owó Yoruba.
A) Aróbọ̀ B) Òwò ṣíṣe C) Ìwà òtítọ́ D) Oúnjẹ jíjẹ
- 11. Ẹni tí ó ta ọjà tí kò jèrè ni won ní o____
A) tàtà jèrè B) gbìyànjú C) ṣòwò sọ́ọ̀ti D) tẹpá mọ́ṣẹ́
- 12. Ìwòyí ni iṣẹ tí ọ̀rọ̀ orúkọ le ṣe,ayafi____
A) olùwà B) òpómúléró C) àbọ̀ D) ẹ̀yán
- 13. 'Bàbá Bọ́lá lọ sí oko'. Kí ni ọrọ orúkọ tí o se iṣẹ́ ẹ̀yán nínú gbólóhùn yìí?
A) Bàbá B) Oko C) lọ D) Bọ́lá
- 14. Èwo ni kìí ṣe álífábẹ̀ẹ̀tì ede Yorùbá
A) b B) o C) a D) ae
- 16. Àmì wo ni ó bá ọ̀rọ̀ yí mu? kirakita--d:d:d:d
A) Kìràkìtà B) Kìrákítà C) kirakitā D) kirákíta
- 17. Àmì wo ni ó bá ọ̀rọ̀ yí mu? Dodo--d:d
A) Dódó B) Dòdò C) Dọ̀dó D) Dodo
- 18. Fáwẹ̀lì Yorùbá pín sí:
A) àìránmúpè ati àrańmúpè B) àfúnupè àti aṣẹ́nupè C) àìgbẹ̀fẹ̀ àti agbẹ̀fẹ̀ D) arẹ́họ́n ati àkùnyùn
- 19. Tọ́ka sí ọ̀rọ̀-orúkọ olùwà nínú gbólóhùn yìí: "Ajá bàbá Olú tí jẹ ẹja náà"
A) Ajá B) náà C) Olú D) bàbá
- 20. "Ojó lọ ra ẹja tí yóò jẹ" Tọ́ka sí ọ̀rọ̀-orúkọ àbọ̀ nínú gbólóhùn yìí.
A) Ojo B) lọ C) ra D) ẹja
- 21. "Adébísí pa ẹran màálu jẹ". Èwo ni ọ̀rọ̀-orúkọ tí ó ṣiṣé ẹ̀yán nínú gbólóhùn yìí?
A) ẹran B) Adébísí C) màálu D) pa
- 22. Kí a tó lè di oníṣòwò,a gbọ́dọ̀ ní nǹkan wọnyí àyàfi____.
A) ìdọmọ ẹgbẹ́ ọlọ́jà B) ní ìmọ̀ nípa ọjà ta fẹ tà C) owó òkòwò D) ẹ̀kọ́sẹ́ kátà-kárà
- 23. Fífún òǹràjà ní díẹ̀ jẹ nínú ọjà tí à ń tà ni à ń pè ní_____.
A) ènì B) ìtọ́wọ̀ C) àwín D) sàn díẹ̀díẹ̀
- 24. Ìwọ̀nyí ni àwọn owó tí a mọ àwọn Yorùbá sì àyàfi_____.
A) Aróbọ̀ B) Owóróbo C) Ìjínigbé D) Aṣọ títa
- 25. ______ni à ń pe àwọn tí n ta ọjà pẹ́ẹ́pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ́.
A) Aláróbò B) Oníwóróbo C) Olóúnjẹ D) Alájàpá
- 26. Ọ̀rọ̀ orúkọ inú gbólóhùn yìí "Motúnráyọ̀ sì tún rápálá wọlé" ni:
A) si B) wọlé C) Motúnráyọ̀ D) tun
- 27. Kọ́ńsónáǹtì tó wà nínú èdè Yorùbá jẹ_____
A) 9 B) 18 C) 10 D) 17
- 28. Èwo ni kọ́ńsónáǹtì tí a fi èjì ètè pè nínú àwọn wọ̀nyí?
A) b B) g C) d D) f
- 29. ___jẹ́ fáwẹ̀lì àyanupẹ̀
A) a B) u C) n D) m
- 30. ___jẹ kọ́ńsónáǹtì àrańmúpè.
A) s B) p C) n D) t
|