- 1. Mélòó ni álífábẹ̀ẹ̀tì konsonanti èdè Yorùbá?
A) 20 B) 11 C) 18 D) 15
- 2. 2000 ní òǹkà Yorùbá ni____
A) Egbèje B) Ogójì C) Ọgbọ̀n D) Ẹgbẹ̀waa
- 3. _____ni orísirísi ọ̀rọ̀ tí à ń lò nínú gbólóhùn
A) Ìsòrí ọ̀rọ̀ B) òwe C) ewì D) gbólóhùn
- 4. Ọ̀rọ̀ tó ń ṣiṣẹ́ Olùwà,àbọ̀, àti ẹ̀yán nínú gbólóhùn èdè Yorùbá ni___
A) Ọ̀rọ̀ ìṣe B) Ọ̀rọ̀ àpónlé C) Ọ̀rọ̀ àpèjúwe D) Ọ̀rọ̀ orúkọ
- 5. Ojú àti imú ń dùn mi. Èwo ni ọ̀rọ̀ àsopọ nínú gbólóhùn yìí?
A) dùn B) oju C) imú D) àti
- 6. Ọnà mélòó ni álífábẹ̀ẹ̀tì èdè Yorùbá pín sí?
A) Mẹ́ta B) Márùn-ún C) Mẹ́rin D) Méjì
- 7. Lẹ́tà fáwẹ̀lì èdè Yorùbá ni_____
A) a,e,ẹ,y,z,u B) a,m,n,y,j,t C) b,d,g,gb,j,k,m D) a,e,ẹ,i,o,ọ,u
- 8. Òpómúléró inú gbólóhùn ni_____
A) Ọrọ orúkọ B) Ọ̀rọ̀ àpónlé C) Ọ̀rọ̀ ìṣe D) Ọ̀rọ̀ onísílébù
- 9. ____ni ọ̀ro tí ó ń tọ́ka sí ìṣèlẹ̀ tàbí ohun ti ẹnìkan ṣe nínú gbólóhùn.
A) Ọ̀rọ̀ àpèjúwe B) Ọ̀rọ̀ àpónlé C) Ọ̀rọ̀ ìṣe D) Ọ̀rọ̀ arọ́pò orúkọ
- 10. 'Mo wá sùgbọ́n ń kò ba yín'. Èwo ni ọ̀rọ̀ àsopọ nínú gbólóhùn yìí?
A) yín B) mo wá C) sùgbón D) ba
- 11. ____ ni àwọn ọ̀rọ̀ tí a fi ń so àwọn ọ̀rọ̀ orúkọ tàbí gbólóhùn pọ̀.
A) Ọ̀rọ̀ atọ́kùn B) Ọ̀rọ̀ ìṣe C) Ọ̀rọ̀ àpónlé D) Ọ̀rọ̀ àsopọ̀
- 12. ____ni egbẹ̀rún ní òǹkà Yorùbá.
A) 10,000 B) 3000 C) 5000 D) 1000
- 13. _____ni àwọn ọ̀rọ̀ tí a fi ń so àwọn ọ̀rọ̀ orúkọ tàbí gbólóhùn pọ̀.
A) Ọ̀rọ̀ àsopọ B) Ọ̀rọ̀ àpèjúwe C) Ọ̀rọ̀ atọ́kùn D) Ọ̀rọ̀ àpọ́nlé
- 14. Kọ́ńsónáǹtì akọ́kọ́ nínú álífábẹ̀ẹ̀tì Yorùbá ni____
A) b B) z C) d D) a
- 15. Lẹ́tà tí ó parí álífábẹ̀ẹ̀tì Yorùbá ni___
A) y B) i C) e D) u
- 16. Álífábẹ̀ẹ̀tì Yorùbá tó wà ní ipò kárùn-ún ni____
A) ẹ B) b C) gb D) f
- 17. Wa ri mi ni Abuja. 'ni' nínú gbólóhùn yi jẹ ọ̀rọ̀____
A) atọ́kùn B) arọ́po orúkọ C) iṣe D) àpọ́nlé
- 18. Fáwẹ̀lì àkọ́kọ́ nínú álífábẹ̀ẹ̀tì Yorùbá ni____
A) i B) a C) ẹ D) o
- 19. Fáwẹ̀lì yìí kìí ṣe ti Yorùbá
A) o B) ọ C) i D) ea
- 20. "Fọláké pupa fòò". fòò nínú gbólóhùn yìí jẹ́ ọ̀rọ̀_____.
A) atọ́kùn B) àpọ́nle C) ìṣe D) ẹ̀yán
- 21. Ọ̀rọ̀-orúkọ àbọ̀ nínú gbólóhùn yìí: "Mo jẹ iyán tán" ni____
A) mo B) tan C) Iyan D) jẹ
- 22. Ọ̀rọ̀-orúkọ tí ó ṣiṣẹ́ ẹ̀yán nínú gbólóhùn yìí: "Ìyàwó Bísí wọ aṣọ òfì" ni____.
A) Ìyá B) wọ C) Bísí D) aṣọ
- 23. _____ni ọ̀rọ̀ tí ó ń tọ́ka iṣẹ tàbí ohun tí ẹnìkan ṣe nínú gbólóhùn.
A) Ọ̀rọ̀ àpèjúwe B) Ọ̀rọ̀ ìṣe C) Ọ̀rọ̀ àpọ́nlẹ́ D) Ọ̀rọ̀ orúkọ
- 24. Ọ̀rọ̀_____ ni a máa n lo rọ́pò ọ̀rọ̀ orúkọ.
A) àpèjúwe B) àsopọ̀ C) arọ́pò orúkọ D) ìṣe
- 25. "Aṣọ funfun ni ìyàwó wọ̀". _____ ni ọ̀rọ̀ àpèjúwe nínú gbólóhùn yìí.
A) Iyawo B) Funfun C) Aṣọ D) ni
- 26. Abi, sùgbọ́n, pẹ̀lú,àti,àmọ́ ni àwọn àpẹẹrẹ ọ̀rọ̀_____.
A) Àsopọ B) Arọ́pò C) Atọ́kùn D) Àpèjúwe
- 27. "Délé ti Ìbàdàn dé lánàá". ____jẹ ọ̀rọ̀ atókùn nínú gbólóhùn yìí
A) ni B) Délé C) ti D) lánàá
- 28. Bí____ kò bá sí nínú gbólóhùn, gbólóhùn bi kò lè ní ìtumọ̀ kíkún.
A) ọ̀rọ̀ orúkọ B) ọ̀rọ̀ ìṣe C) ọ̀rọ̀ àpèjúwe D) ọ̀rọ̀ atọ́kùn
|